Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,162,430 members, 7,850,517 topics. Date: Wednesday, 05 June 2024 at 12:00 AM

Richylaw's Posts

Nairaland Forum / Richylaw's Profile / Richylaw's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) (of 17 pages)

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:02pm On Jul 12, 2007
Niteangel ati Busy bee, e dakun e je ki a ti ibi pelebe mu ole je o. Sebi eyin na mo wipe omo osan lo ma n ko kumo ba iya re. E ma je ki a titori enikan ti ko niran fi ori okun to layo to si larinrin yi sile o. Mo ba Oloye Segoye jiroro lori oro awon omo ti a ko ko, to wa n gbe ile ola ta ni ita gbangba yi, a si ti gbimo po wipe Oluaye Oba Seun Osewa yio fi imu gbogbo won danrin. Bi e ba lee mu lo ninu imoran mi, e mu oju kuro lara awon eranko wonyi ki e si ma a ba awon eniyan gidi je aye oba lo ni ile yi o. awon amunibuni eran Ibiye dede.

Awon wonyi ni Judasi tabi omo Woli Eli ni inu bibeli
Awon na ni Namurutu ninu Al-quran, iya ni won yio je gbehin
Awon si ni Laalu ninu asa ibile ti Yoruba

Aso funfun lawa wo, eje ki a jinna si alabata, niwon igba ti o ti je wipe epo la gbe ka ori , e je ki a jinna si oniyangi.
Signed
Baale Yoruba of Nairaland
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:15pm On Jul 11, 2007
singing
Aderupoko /2x
ko ni lo
ko ni je ni ti o lo lo
aderupoko

Mishoo, mo ni lati jewo fun o wipe n ko mo bi n o se dekun erin ti mo n rin lowolowo bayi, koda mo n ri itara ati ibinu ninu oro ti o ko sile. Iru awon egbon bayi po kaakaakiri. Bo si se wa ni liki lowa ni gbanja. Bi o se ri si abo be na lowa lokunrin. suuru loo se o. Ri daju wipe o n  fi ohun gbogbo te afesona re lorun ki o si ma fi aaye sile fesu rara lati apa odo re , bope boya , laipe laijina egbon afesona re ti mo le pe oruko re ni aderupoko yi yi o wa ibikan wo si.

Akiyesi: o dabi eni wipe owe meji ni o yipo mo ra won ninu  oro re
Da bi mo se da ni, elewa sapon.

Ekinni : da bi mo ti da ti i ko le ewe ti panu
Ekeji: Se bi o ti mo elewa saapon.
Lai si ani ani o damiloju wipe ti akoko ni yi ba afiwe oro re lo.
(ranti wipe awe oke yi kii se eni ti a n fun lesi o)
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:01pm On Jul 11, 2007
mishoo:

E jowo e bami da si oro yi:
Ni aye ode isin, se dandan ni ki egbon lo si ile oko saaju aburo ni.
Mo setan lati gbe arewa mi wole, ni egbon re ba faariga pe oun ko iti lo ile oko oo.

O ma n dun mi ti mo ba ti n ri iru awon oran bayi. Se ki a pe egbon iyawo re ni "ato le oko ma lo ni" abi ka pe ni "adina gba oku" Bo tile je wipe ibi gbogbo la n k'adiye ale , emi iba parowa fun o wipe ki o fi edo lori oronro fun igba die na. Koda , igbese yi ko ni je ki egbon iyawo re fi okunrin sako mo, yio si wa woroko fi sada laipe laijina. Suuru lo laye o, ranti wipe aki i kanju tu olu oran nitori wipe igba re ko to ni se lobe. Ma jeki awon ara ile iyawo afesona re ro wipe onigberaga ni o o . Fi aye die sile si
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:10am On Jul 11, 2007
Piri lolongo ji. Ara mi le ju tanalo. O seun Desorlah. Baale re Segoye nko?
Iyalaje ati Mishoo mo n ri owo yin o, omo ajananku ko jo arara omo ti ekun ba bi ekun ni o jo.
Iyalode Ika, Inu ifa lati yo Fatimo, inu bante lati yo beliti, inu oro kan lati n yo oro miran, ni inu ede yoruba, owe wa, asayan oro wa , afiwe wa, agbekale ede si wa pelu. Ewa ede ko gbehin rara, ewi , ijala ere ode, Iwi egungun, iyere ifa, rara, ege ati bebe lo.Sugbon ninu ede yi na ewe, agbara ede wa, iru eyi ti a le toka si wipe o je bi i ofo , ayajo, ogede. Ohun a ni la a gbe laruge o.


Si gbogbo ara abule
Igba eke ni fowo di ile,
igba alamu ni fowo dogiri
Awon alale yio di yin mu o
E o ni jabo o
E o ni jafo o
E o ni goke gegele re lule , fonka yanga bi awo aifokan moju to o
ASE WA
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:28pm On Jul 10, 2007
lol
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:27pm On Jul 10, 2007
common Ika, nibo lo ti ri ogun. Ogede,ayajo ati ofo lenu awon wolo ti n gbo yen. Anyway sha, ti o ba je be, o dabi eni wipe adura ni won fi n se fun ara won o.

Nana, yangan is agbado yiyan, ROASTED/TOASTED/SMOKED CORN IN IT'S DRIED STATE
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:29pm On Jul 10, 2007
"If you learn from defeat, you haven't really lost."

Desorlah, bi ki obinrin la okunrin mole loju ija ko sa o grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:32am On Jul 10, 2007
Aku ojumo o, gbogbo ara abule e n le o. Ara o le bi. A de tun ku oro orile ede wa ati eto iselu o.
Nipa ti oro awe chichi yen , e fi sile, bi aja ba ti ya digbolugi ki i pe pupo to fi n teri gbaso. O ti gbagbe wipe " bayi la n se nihin , ewo ile ibo mi i ni". O ti fihan wa gbangbagbangba ibi ti iran re ti wa. Nje e mo nkan kan , aibikita loogun ta fi n mu iru won, e je ki gbogbo wa dake si oro re, nigba  ti o ba tun soro ti ko ri esi lati odo eni kankan, ohun funrarare yio mo wipe ohun ti n gun igi re koja ewe.
Oloye segoye, desorlah,tafari, mishoo, debosky , nana hope you are all doing fine? Iyalaje , a to joye koto joye mo ki wo na o, mo si tun gbadun ohun ede ti ayan re n fi gongo pe jade o, lagbara eledua a o ma semi ohun rere ni o 
Oduduwa a gbe wa o . ASE.
IRE
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:32pm On Jul 09, 2007
Desorlah , ko to ope rara o, ki ni a jo je omo kaaro ojiire fun? Iyi ti o wa nibe na niyen o. Eku inawo ati inara o. awon Oloye titun na n ko, o damiloju wipe o re ara die  lehin wahala iwuye ni.
Israelite, daadaa ni mo wa o, se ile dun OTUNBA ODO abi? E kuu aayan na.
debosky, Kaabo o, nigbati ti mo ri o lori mohunmaworan lori papa ti Victoria, mo lero wipe ibeji re ni o lo woran ni ase iwo gangan ni. Gbogbo ekan ilu lo n ki o kaabo pada o
Iyalaje, sebi a ti so wipe iwon eku ni won ite, eto ti o ye ni wipe ki Madam Orobo san owo eni meji o, abi ki lo n wo ti o fi di firigbon be. Ni ilu oba , aye po ninu oko fun iru won, ipese ti o si peye ko tile le fi aye sile fun kondo lati se ise iwosi kankan. Sugbon ni ilu ti ko lofin ese o si o
Nite Angel, inu mi yio dun lati gba o  lalejo ti iwo ba n bo si agbegbe ti mo n gbe o.
TV/Movies / Re: The Most Violent Or Action Packed Movie Ever by richylaw(m): 6:12pm On Jul 08, 2007
300 and Apocalypto, this films roock- quite violent
Art, Graphics & Video / Re: Software Used For Animated TV Commercials? by richylaw(m): 6:06pm On Jul 08, 2007
deltree:

can i get these softwares at computer village?


some are available at computer village , but not all te time
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 6:00pm On Jul 08, 2007
whiteroses:

@richylaw, se iyen ni o n kaelara, oo wa wo orisiirisi iwa egbin to oju mi ti ri ni nairalandi yii kiki egbin ni, paapajulo ti sexisuality yen illegal ni, so maa binu.

Bi nu we!? Oro iru won ko jo mi loju mo. Emi na ti ri kisa ni abala ti sexuality, sugbon n o ni fe ki awe yen da epo si aso ala wa ni abule yi ni o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:57pm On Jul 08, 2007
iyalaje:

Motika dire nipa richylaw. Eniti oleto ki oje Baale gangan ni. Inu odo eyiti eti npon omi naa koni gbe rara. Ogbon po pupo. cry tongue

Bo jo ba yo , akari aye
Alakanle ni t'osumare
Tutu lomi lenu eja
Iyalaje, aye o ni ri o gbe se
Oseun o ku ayesi mi
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:39am On Jul 08, 2007
Ma be igi fun Moji ni, fun iru iwa elegbin ti o si lewu fun awujo awon omo adarihurun ti o hu yii !
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:06am On Jul 08, 2007
o tun ku nibon n ro

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:05am On Jul 08, 2007
eyi to ku

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:04am On Jul 08, 2007
Eyi ni aworan bii iwuye Segoye se lo,
awon eniyan pataki bii haywhy, nana, ayefele, omogenaija, Israelite, Olufidu, Dis guy, Mishoo, Mukina, ati be be lo ni o wa ni be o. Ko da Oluaye , Kabiesi Seun Osewa na o gbehin.

OLOYE SEGOYE , ABOBAJIRO TI YORUBA OF NAIRALAND OYE AMORI O. ASE.

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:53pm On Jul 07, 2007
IWURE SEGOYE CONTINUE

Awon omo Oya, oyarayun
Awon omo Oya, oyarayun
Awon omo Oya, oyara yunrun
Awon ni won ba iya iku nigbe loja iyunmekun
Nitori akoro ori eran
Iku gbo iku han bi agoro ide, bi agoro Ide
Iku de ori apa, apa ni ori ohun o gba iku duro
Apa na igbiramu hale
Iku de ori Oro, Oro ni ori ohun o gba iku duro
Oro igbiramu hale
Iku de ori Iroko, Iroko ni ori ohun o gba iku duro
Iroko na igbiramu hale
Ayunre nikan logbon
To mu eji ku eta
To roko alawo
Bawo ni iku ti o nbo o se ni pa ohun
La ba difa fun ayunre
Iku de ori Ayunre
L’ayunre ba ye be kese
N’iku ba fige sole
Iku ye lori re loni o Segoye
Bi elegede ba yo ewe ogun gbagbara
Ile ni i fi ti e na
Bi toteregun bay o ewe ogun gbagbara
Ile ni i fi ti e na
Bolo bolo bolo l’omode n roko osepotu
Bolo ni Segoye o ma yobo lowo Iku ati ota o
ASE WA.
IRE

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:40pm On Jul 07, 2007
Iwure fun Oloye Segoye

Epo ape lo ni waa pe laye
Epo orogbo lo ni wa a gbo laye
Igba lewe rere
igba lewe akisa
biku ba yo wo si o
Segoye iku a fowo na le porogodo
Bi ku ba yo ese si o
Segoye, iku a fe se jan le porogodo
omo owo ki i ku loju owo
omo ese kii ku loju ese.
O o ni je oye yi ku o
Ase.

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:33pm On Jul 07, 2007
israelite:

Eku asale o ejo, eku odun ojo eni oo. 07 07 07

ah Isrealite ba wo ni, awon t i i imesi n ko, oye Segoye ni ko je ki n le yoju si ibi oye re ni imesi ile o. Awon aworan ti a ya na ni e o ma ri laipe
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:05pm On Jul 07, 2007
segoye o ku ori ire o
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:04pm On Jul 07, 2007
heeeeeeee
Muso muso muso    MUSOOOOO

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:13am On Jul 07, 2007
SEGOYEHere comes the town cryer to announce a good news
Atoto arere o
kere o , kere o , ki eku ile ko gbo ko so fun toko.
Ki agbon oke gbo ko si mu irohin kan ti isale
Nipa ase lati enu olori oko
Oluaye Are Naira land Seun Osewa
Baale Yoruba Thread of Naira land, Richylaw ( Epo n sa fun Oniyangi I) ni ki n so fun yin pe .
Awon igbimo ilu yi o fi ewe oye le arakunrin Segoye , oko Desorlah lori ni irole oni, ojo abameta, ojo keje osu yi.
Oloye Abobajiro la o si ma pe e. Mo wii re abi n ko wi i re
ko ko ko

Culture / Re: Yoruba Proverb Competition by richylaw(m): 3:09pm On Jul 06, 2007
laudate:

Nice one, Richylaw. Wish others would emulate your example. sad

Thanks for the compliment.

The challenge is still on, I may not be compel to roll out the next ten until this one is answered

CHALLENGE

Bo ba ku apa kan adan , ?
Art, Graphics & Video / Re: Criticise This Design by richylaw(m): 12:06pm On Jul 06, 2007
Just use a light shade glow / shadow for your excellence stamp and you should be scoring 65%. Good one anyway.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:59am On Jul 06, 2007
desorlah:

Hi everyone, se wapa, se daada ni mo ba yin.

Baale, Segoye2, Nana, ika6 etc, hope u're ok.


Mo wapa baje grin
And u? Mo lero wipe emo wipe ola ni iwuye yin sha.?
Culture / Re: Origin Of Pidgin English by richylaw(m): 1:50pm On Jul 05, 2007
Take a look at this link you should get all your immediate needs as per this topic

http://en.wikipedia.org/wiki/Nigerian_Pidgin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:01pm On Jul 05, 2007
segoye2:

Baale, Eku ile oo, oro awon awe yi ka ma ma, o de se mi laanu pe oro ti ko ni ila akaye ni won so. OMODE SO Ko SI GBO, WE RE LON YA YEN!.

fi won sile, ki o ma woye
Culture / Re: Yoruba Proverb Competition by richylaw(m): 12:44pm On Jul 05, 2007
Having translated my last two proverbs, I flipped through all the previous pages and I feel more impressed than what I actually felt initially. But does it mean these are all the proverbs we have in yorubaland? No way, do not relent guys, I don't think this thread should die like this.
ok , I have promised myself to roll in a hundred conc yoruba proverbs which no one had sent in on this thread , ten at a time and one as a general challenge to every one as per ''pari owe yi''

Lets go

A. Olohun lo lohun , agbo isale lo ni ohu ohu
The owner is still the owner, the lower jaw is used to frequent movement
Meaning: Practice makes a professional, the professional tends to do it best

B. Olurogbo kii jo lasan , onilu re n be la le odo.
The water lilies does not dance to vague rhythm, it is certain the drummer lies low on the river bed
Meaning: For every success there is a significant backup,For every action , there is is a reaction

C. Atiranmu gangan ko seyin ekanan
The eloquence of the talking drum may not be achieved in the absence of the finger nails
Meaning: Same as above

D. San an laarin , aje ni mu ni pekoro
Our focus and foresight has a target, but success anxiety prompts for distractions along the route.

E. Lowe lowe la n lulu agidigbo, ologbon lo n jo , omoran ni tumo re, ewe koko la fi se awo re, igi ganmu ganmu la a fi i lu.Afoju ni lu, aditi ni i le orin si.
The agidigbo drum (aka bata) speaks proverbs, the wise dance to it, the sages translates it. The cocoyam leave is the drum’s skin, the thorny sticks are used for the beatings.The blind beats , the deaf and dumb singsMeaning: Always pick wisdom out of life , remember out of mere statement a world shaking solution may be proffered.

F. Bi a ba dana loko, mojala a sofofo nile
When the debris is burnt in the farm, the ashes residue comes to report at home
Meaning:Never see anything you do as secret, the output product reveals the secret later

G. Operekete n dagba, inu adamo n baje, a di baba tan inu n bi won.
The palm frond fetcher gets annoyed as the young palmtree grows taller.
Enemies are not happy seeing us being successful.


H. Kekere la a ti pekan iroko, to ba dagba tan apa ki ka mo
The branches of iroko tree are better prunned while young, as it will be difficult when fully grown

I. Bi ebiti o pa eku , a fi eyin fun eleyin
If the trap refuses to catch the rat, then it should be capable of returning the palm fruit to the trap owner.
Meaning : If you can not make progress on a target, just leave it as you met it.

J. Agbalagba lo to oro fo, oba nla lo to eyin erin fon
The elders holds the mantle to speak wisdom, only the mighty kings blows the elephant tusk (ivory)

CHALLENGE
Bo ba ku apa kan adan ,

1 Like 1 Share

Culture / Re: Yoruba Proverb Competition by richylaw(m): 12:31pm On Jul 05, 2007
richylaw:

opalanba lowo, kumo lehin orun, se boju se ri re ta n jobi loja oba.
Beaten with batons and club, I never knew you were like this while we still frolic and entertain each others with kolanuts at the market square
Used to ward off a back stabber

richylaw:

A i lora ogongo ko se e fi we ti adigbonnanku
The insufficiency of fats in the ostrich can still not be compared to the total lack in other ratites
olympic is not to win but just to participate! grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:48pm On Jul 04, 2007
israelite:

Ekanso oo, oku ijo mete, eku ayirini ayibere eni, molerope opolol ninu yin lomo pe ojo iwuye mi ku ijo mete gege bi OTUNBA ODO ni okemesi ipinle ekiti emagberedi,

Ki oluwa mu ojo ro o
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:47pm On Jul 04, 2007
Mishoo , o ku faaji o, ibi ise ni mo wa lowolowo bayi , bo tile je wipe mo n se, lase kara, mo fi okun ''asorokele-si-ni leti'' mi si eti mo si n fi ori jo si orin Yinka Ayefele ( Next Level)

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) (of 17 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 51
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.