Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / NewStats: 3,162,388 members, 7,850,394 topics. Date: Tuesday, 04 June 2024 at 08:23 PM |
Nairaland Forum / Richylaw's Profile / Richylaw's Posts
(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) (13) (14) (of 17 pages)
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:31am On Jun 20, 2007 |
Ara le o , o seun |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:00am On Jun 20, 2007 |
desorlah: Bo o ni desorlah , se alafia ni iwo ati oko re wa bi?. E ku imura sile o. Ipade ti mo lo lo mu ki o re mi die. Sugbon ara tile pada o. Mo ri bi iyalode se n se ewa agonyin, ati bi alraheem na se n je. E ku akitiyan o. |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:07pm On Jun 18, 2007 |
Segoye , o ku oro ilu. Gbogbo akitiyan re ni mo si ri pelu, nigbati mo lo sii ipade lobaloba. Gbogbo aba ti Tafari n da na ni mo si gbo nipa re. Mo se akiyesi abewo Olorioko Oluaye Nairaland Oba Seun funrarare, bi o tile je pe ko duro pe rara. Gbogbo Ile ni mo ki e ku aduro ti o. Wayi mo ti de pada o , aya ti be sile , o fe sare. Desorlah ku ise o. Ika, nana, minute, Nite angel, gnature, ikomi, muki e ku akitiyan o Segoye o ku imura ojo Satide ti o n bo yi o. Mo gbo wipe ojo iwuye re niyen. Ki oluwa mu ojo ko layo. Debosky o ku imura sile ti e na . Gbogbo ara ile, e ku ile o . |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:44am On Jun 16, 2007 |
mo n lo si ipade lobaloba. ti mo ba de a de ma rira |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 8:15pm On Jun 15, 2007 |
nana: se osan ni ni odo tiwo na |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 8:11pm On Jun 15, 2007 |
omogenaija, kaasan o, mo mo wipe wakati maarun lowa laarin emi ati iwo nitori ago mejo ale ti koja lodo temi , sugbon met osan loje lodo tire. Awamaridi ise olodumare! |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 7:36pm On Jun 15, 2007 |
desorlah: iwo gan alara pa mi leerin. Se oko re wa je arobo ni ti a o ma wa kiri bi abere. O ye ki o mo wipe alakitiyan ati akaramasiki ni o je , boya o ba se eto ilu lo tabi gegebi debosky ti so boya o sare de ode emu. Apara gba ni mo n da o. Abi ko dara ki a ma ranti igba ewe lekookan ni? |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 7:23pm On Jun 15, 2007 |
Iro o, ko si ni aafin o, wo abe kobodu ati kapeti boya o ti sun lo si be ni |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:19pm On Jun 15, 2007 |
koda o ri ro daadaa o. ha ha , baba olowo. Ninu gbogbo ile ise ti o n be ti eniyan lee da sile , eyi ti won yi o ti maa se oti lile ni o wa wu o lokan lati da si ilu wa. uhn, oro sunnukun! Emi nikan ko ni mo ni oro yi o, gbogbo ilu ni yi o da si. GBOGBO EYIN ARA ILU E BA WA DA SI ORO YI O, SE KI A GBA LAAYE A BI KI A KO EHIN ETI SI ORO ILE ISE OTI LILE NI ILU WA? |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:29pm On Jun 15, 2007 |
Mishoo , n le o, se alaafia ni? Ile nko? |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:08pm On Jun 15, 2007 |
Fi okanbale , oro re n be loju opon ijiroro. A o kan si o laipe |
Culture / Re: Are You Proud To Be A Nigerian? by richylaw(m): 2:06pm On Jun 15, 2007 |
Forever grateful to God for placing me on this land Nigeria, we hail thee, Our own dear native land, Though tribe and tongue may differ, In brotherhood we stand, Nigerians all, and proud to serve our sovereign motherland. Our flag shall be a symbol, That truth and justice reign, In peace or battle honoured, And this we count as gain To hand on to our children A banner without stain O Lord of all creation, Grant this our one request Help us to build a nation And so, with peace and plenty, Where no man is oppressed |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:41pm On Jun 15, 2007 |
tafari: Arakunrin Tafari , okunrin meta. omo oluwo olodo oba kankan sansan omo olodo kan oteere , a san wereke wereke omo olodo kan otara , a san waraka waraka atenigbola amule t'olufi Moleye merin otere, Mo labiye fo merin kan otaara B'agbe ba ti gbe aro a lo n lo igberi okun lo re jaye B'aluko ba ti gbe osun ti e a lo n lo osa lo yotomi Bi Lekeleke ba bu sese efun tan a a foju orun tan kiniwin Gbangba lewu , gbangba laso Bi odidere ba ti hu ikode mu sewa tan a ni ile Iwo ya Iwo omo atenigbore. Inu mi dun wipe ilu Iwo ni o ti wa. Ni igba ikoko mi mo gbe ni Ilu Iwo fun Odun meji laarin odun 1978 si 1980, adugbo oke afo ni mo si gbe. Ilu to gbaju gbaja ni ile kaaro ojiire ni ilu re o. Nipa ti awon oko ayokele ati oro owo yi , jawo n be! ori ade ti Ilu Yoruba fun Nairaland ko ni gba iru re, Oko ofurufu Oke aimoye ni mo ko jo si ori papa lagbala mi, esin lo bi rere, eru ati iwofa ko ni ye, awon oko awoyanu gba esinsin lalejo n be lori iduro fun baba (Emi Akanbi,onile ola, ibu owo ,okunrin gbangba , aboogun gbangba laya! ) . Bi awon agba ilu ba ri wipe oye to si o , a o kan si o lehin ti segoye ati debosky ba je oye tan. Ko je bo ti je. Ire |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:02pm On Jun 15, 2007 |
Segoye ati Desorlah , e n le o. A a jibi. Mo wa laafin o mo n reti yin ti e ba fe wa. Tafari, Tafari , Tafari oodua o fe be, abetele loruko ohun ti o fe se yi. Awon alale ati isese ko o. O san ki a doju ko ogun lori inaro ki a si ku sibe ju ki a gba ominira lori ikunle lo. Bintin bayi ni egberun lona egberun lona egberun owo re je legbe iyi ati oriyin ti olotito ma n gba ti o ba duro sinsin. E je ki a ranti awon ara ana ti won ti fi abetele ta ogun ini Orile-ede wa fun awon ara oke ohun, irora re la n ke titi di oni. Tafari o se mi laanu pupo wipe n ko ni agbara kankan lati ran o lowo bi iwo ko ba le e dahun awon ibere ti a gbe ka iwaju re yii. Mo si mo wipe o kan fe fa mi lese lasan ni, akikanju okunrin ni o , o si ni doju ti ile kaaro ojire, idahun si awon ibere perete yii n jenu wujewuje ni i isale ikun re ,o kan n tiju ni. Eni ti o kun oju osuwon ni yio je oye ilu yi o. Tafari gbera nile o dide , ki o fi omo akin han |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 7:33pm On Jun 14, 2007 |
debosky: ma kanju rara iwo na ni o kan lehin segoye ati desorlah , nitori na ki e lo ma ko apo owo jo o |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 7:28pm On Jun 14, 2007 |
Ah eyin eyan mi, iyalode ikamefa, Mishoo okunrin meje, debosky oloye to n bo lona ati Nana eyin ni. Mi o mo pe eyin ni o. E ku bi oju ojo se ri yi . Awon ara ile n ko , e si tun ku ojulona iwuye ore wa o Segoye |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 7:25pm On Jun 14, 2007 |
ha, ha, ha , eyin wo le n pariwo pipipi bantabanta lehin aafin ba n, e o mo pe baale n reju ni yewu ni? |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:15pm On Jun 14, 2007 |
tafari: Alagba Tafari, idunu nla ni o n je fun mi lati ri wipe oye ilu wa yii n wu iwo na . O si ti di dandan ki o ri oye je. Mo ti ba awon oloye ilu to ku soro nipa igbese nla yi, won si ti fi enu ko wipe kii a se idanwo fun o. Ti o ba ti we yan kainkain , o daju wipe kosewu legberun eko o. IDANWO FUN TAFARI: A. Pari owe yi: 1. Ailora ogongo, 2. Datoro,datoro, datoro, agba ti o da toro, 3. Idi ni iku igbin,, 4. Onibaje ko won,, 5. A kii bara eni tan ,, B. Omo ilu wo ni o? C. Fun wa ni ila maarun pere ninu oriki orile ilu tabi iseda ebi yin. Ogbeni Tafari , awon ibeere jekojeko yi ni mo nilo esi fun , lehin eyi o di dandan ki o joye ni Ilu Yoruba yi. segoye2: A fi bi eni wipe o gba enu mi soro, mo sese fe beere idi ti a kii fi ri oluaye Ile Naira Alagba Seun Osewa ni abala ti yoruba, mo sebi oruko yoruba ni Seun, ki wa lode? O di dandan ki o wa fun ti oye re o. Mosi tun fi asiko yi ro Segoye ati iyawo re desorlah wipe ki e fi aworan ara yin tabi eda re sowo ranse si baale o, awon oniroyin nilo re. on a more serious note |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:25am On Jun 14, 2007 |
To o mo ti gbo o. Gbo na ibo ni oko re wa ri, ba mi so fun wipe ki o wa laafin o. |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:45am On Jun 14, 2007 |
desorlah: Awon olori na n ki o o, won ni ki n so fun o wipe ki o ma gbagbe gbogbo awon eto ti o ye ni sise fun ti oye yii o, bii aso elegbe joda, ipese onje- ikoko alati, aperin,adogan, iwakara, orogun, igbako, odo iyan , olota, arinjojo, ewe eran, ewe gbodogi ati bebelo o. Nitori oko re Segoye ti leri leka wipe ohun yio file ile pon oti , ohun o si fi ona roka loja oye yi o, o si da mi loju wipe e ko ni doju timi. |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:26am On Jun 14, 2007 |
desorlah: Gbe ra nile o dide, obinrin daadaa, aya re loode oko re. Koko lara ota n le o . Iji a ji loni ka bare pade o. A o ni ta wo na kato jaye, a o ni taraka ka to je o. Ile Naira yi o ni gbona mo wa o. Ilu Yoruba ti a si tun wa yi o ni daru o. Desorlah o ku akitiyan iwuye to n bo dede lona yi o. Yio ba wa layo. Ire. Ire kanka |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:32am On Jun 14, 2007 |
segoye2: O ma seun mi Oloye titun Segoye, abi o ri nkan ni ? A n pe awon eranko oniwo, nigbin ba yoju , o ni," e ma gbagbe mi o!, e ma gbagbe mi o". Ki la gbe , ki le ju. Nigba ti mo ma bere oro , 'KINI' ni mo to ka si, nje mo ti wa soju bayi ni. Bi mo se wa di oya lowo arakunrin ti o pe ara re ni Ajayi yi ni ko ye mi o. ajayi1: Arakunrin jowo jeki ewe omo re je olufimo o, Nje o ti ri mi ri ni , abi o pade mi loja ti lana. Nitori bi mo se di oya ati Igala ni owo re yi ya mi lenu o. Irinisi nii ise ni lojo o. Emi kii se omo ile ti a n fi eni be rara. Awon oro ati apara ti o si mu ogbon wa ni awon olori pipe ti o ba ni aagbon okun oro yii si n fi se ewa ede. Bi mo ba bere oro ti o ru mi loju kii se ese rara. Nje o ti le mo bi Babasuwe se je si mi , abi o mo iha ti mo ko si ni. Gbaran mi deleru ti e yii o le e pe o o. Niwon igba ti mi o ba ti ta oko oro isokuso si o ri, ti mi o si gbe enu samuga si o , DAKUN foye soro si mi o |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:28pm On Jun 13, 2007 |
segoye2: uhn baba Suwe! Mr Babatunde Omidina, nibo ni o ti pade re na, inu mi yio dun ti o ba lee wa fun iwuye o. Sugbon o dabi eni wipe won ni 'KINI' ni won wa |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:25pm On Jun 13, 2007 |
Mo tun ki gbogbo wa lekan si wipe a ku oju lona o. Adun a kari o. Mo ri wipe enu iyalode Ika6 wo hoho nigbati won ri esi Muki si mi. Baale na o je bee, ogun(juju) lo po |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:55pm On Jun 12, 2007 |
mukina2: Yes now, what else? after all the your warm, wonderous and immeasurable efforts on this thread. Nite Angel: Bawo ni jare Angeli abiye fo lale, alele na ni a ma n ri yin , e ku abo si ori eto o. Ewe akoko eyi ti a n pe ni ewe oye wa ni scotland o. Bi iwo ko ba gbagbo duro di ojo iwuye segoye o. Iyalenu nla ni yio je fun o |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:28pm On Jun 12, 2007 |
mukina2: You try well well .Keep it up. Just like I said when you get to the palace I will get a good trainer for you take you up. Eyin eniyan mi oro ti so ara re o |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:24pm On Jun 12, 2007 |
mukina2: Mo wa pa o oniyeye ni omode yi o, bi o se ma n se bi eni ti ko le je eko kan tan nu. Mukina2, don't be afraid , you should be pleased that you're actually turning to a celebrity overnight, courtesy Baale Yoruba of Nairaland. Just sit down and look while your luggage is being moved into the palace. |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:16pm On Jun 12, 2007 |
Segoye, awon iko onirohin wa si aafin loni lati fi oro wa mi lenu wo lori oye titun ti a fe fi o je, mo si ti se gbogbo alaaye ni kikun fun won. Nigbati ti won nlo, won beere fun foto re lati lee fi gbe irohin jade lori i awon iwe irohin Atoka ati Odidere Ayekoto sugbon iyalenu lo je la ti rii wipe photo ti o fe jo ti Obesere ti o wa ni oju iwe oro nipa re , ko si nibe mo, aworan orile ede naijiria losi wa nibe. Jowo o se pataki fun wa leleye-o-soka lati ni photo re fun oro oye yi o. Bi o tile je wipe Desorlah ko jale ko wo ewu ninu photo tire, a fun awon onirohin bee. |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:02pm On Jun 12, 2007 |
Gege bi e ti mo wipe baale kii se olojukokoro. Emi ki gbese le eniti ko ba ye ki n gbese le o. eyi ti o fe sele yi, ifa lo wibe o. iyawo kii po ju fun baba laafin o lekan si mo ki gbgbo wa ku oju lona iwuye segoye , oloye mi titun o. Bi ojo oye yii ba se ri ni a o se mo boya o ye ki a fun iyawo re desorlah na loye o. ire o |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:52pm On Jun 12, 2007 |
mishoo: Mishoo temi ni kan soso, jowo ma wo nkan kan ninu ogba o, awon apayan ati gbomogbomo lowa nibe . Mo si ti so fun awon ode ati fijilante ilu ki won ma so inu ogba na. Enikeni ti a ba si mu ni a o fi imu re danrin. Emi ko ni fe ki ore baale tooto je iya ti ko mowo mese o. |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:49pm On Jun 12, 2007 |
E ku atotonu o gbogbo eyin mutumuwa. Iyalenu nla nla lo je fun mi lati ka orisirisi ohun ti eyin ilu nso nipa baale o. E jowo ta ni o waye adagba ma labe na. Gbogbo eyin ilu n yotomi laarin ara yin , e wa ni ki baale kan ma se eto ilu lasan , to, oti da o. Iyalode Ikamefa, ti a ba so wipe omi lo ma se eja jinna a o ni iro ni, o si tun n ji baale lese. Sebi o wa ninu aafin nigba ti ifa so wipe arabinrin ti ko ba ti gbo ede ni ki baale fi se iyawo kekere. Ki wa lode ti o fi wa fe ma se olori alatako si mi. Oodua o fe be o. Won tile so fun mi wipe ohun fi oju di ogun baale. Kai mo danwo. Bi omode ba dari so apa, apa a pa o! Debosky, nigba wo lajo sapero lori oro nana, baale eleyi ki i se "agbalowomeri" o, nitori oruko Ilu yi kii se "Jontolo", Nairaland ni a mo si. Emi o gbese le Nana o. Nigba ti asiko ba pe, ti o ba wu awon alale, funra ara re ni yio fi ese rin wa si aafin o. Nitorina ma puro mo baale o, a i jebe awon igbimo le e le o kuro nilu o. Iwo ati Ayefele ni e jo n seto Nana , emi o si binu si. Sugbon emi ko ni fe ki e ti owo ala yin bepo o Segoye, ranti wipe o ti ba ifa mule o, ma se daba lati da a ifa. Se o mo wipe iwo ni oye idile yin kan laafin mi, "Abobajiro Yoruba of Nairaland". Emi ko ni fe ki o wu iwa ti ko ni je ki a ja ewe oye le o lori o. Oro re ati akitiyan lati gbeja mi han si mi, sugbon nibo lo ti ri 'JIGA' won so wipe o ni wa so jiga lu ese baale ti o ba gbe ese le Mukina2 Agbedo, iwo o mo idi ti won fi n pe sango lorisa ti bu ra re san woinwoin ni? Se o ro wipe ota ibon nikan ni ayeta wa fun ni? abi oro wipe ada ati obe nikan ni a n lo okigbe fun. Dakun o, bi o se n se daadaa ni ki o ma se o. Desorlah, kini baale se fun yin o. Ti e ba fe mo idi oro ti e ba nile lori bii ifa se so wipe ki baale gbe ese le Mukina2, ma ran awon akoda mi wa si ile yin ni owo tanmo oko pelu oko bobinibolojo ayokele ti e mo si 'stretch Limo' ki won o gbe yin wa si afin fun ipade ranpe. ki o to di igba na e tu gbogbo eru iyawo ti e ti di kiakia o Ni akotan e je alagbara ninu oluwa. Oro mi ko lopin Baale of Yoruba Thread. Ire |
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:29pm On Jun 11, 2007 |
segoye2: uhn atelewo eni kii tan ni i je |
(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) (13) (14) (of 17 pages)
(Go Up)
Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 70 |