Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,162,440 members, 7,850,539 topics. Date: Wednesday, 05 June 2024 at 01:32 AM

Richylaw's Posts

Nairaland Forum / Richylaw's Profile / Richylaw's Posts

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 17 pages)

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 8:57pm On Aug 21, 2007
Tafari n bere wipe nibo ni awon oloye wa.
So pe n saawo!
Nigba ti aare orile ede Mexico ri wipe aja ati iji n ja ni orile ede oun, ki lo se? O so fun ogbeni Bush ati akeegbe re ti won lo se ipade ni odo re ni Canada wipe o n lo ile.
Be gele ni oro ibi yi naa se ri, ogun ti o be sile ti o si gbona girigiri ni nairaland lowolowo bayi ni gbogbo awon oloye lo lati lo woran tabi lati petu si awon iko mejeeji ninu (NIN and NID). Alagba Debosky ti se akikanju ko ja ala ninu irohin ese kuku ti won n fun awon eniyan, gbankogbi ede oyinbo ati awon oro alufansa meriiri ni o si n bo lule lolokan ojokan! A dupe ija ti pari o
Amo sa emi ti se iwon ti mo le se mo si ti pada de ile o. Mo wa laafin n o si lo ibi kankan mo.
https://www.nairaland.com/nigeria/topic-72759.0.html
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:38pm On Aug 17, 2007
omoge:

boju boju oo e
oloro nbo
epara mo
se ki she
shesheshe
enikeni to ba mu
apa je oo


ekaro ooooooooo
Omoge , kaaro o, o lee shi o, sugbon mo pa eniyan je o.

pat4:

Can someone tell me what is this all about?.Every body is saying something i don't really understand, What is this test all about?

Pat4 you are welcome on board as you can see the topic , 'If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! ' so is the thread enjoy.
Religion / Re: Drop Your Prayer Point Here. by richylaw(m): 2:32pm On Aug 17, 2007
To you oh Lord , I give praise for your immeasurable love, protection and divine responses to solve my life problems.
It is only in you forgives comes real and I lean on thee to continue to be my forgiving father
Give me the grace to continue in you and live the Christ-like way
Harken unto my voice and actualise a physical testimony of the victory you have given unto me spiritually
For I shall be the head and not the tail; Lord lift my hands and head high in all my undertaking
Let me soar high as you've given me the strength to mount wings like eagle
All stumbling blocks and debarring obstacle to my progress and success be destroyed by fire right now in Jesus name
Lord , help Nigeria through her stormy voyage to be the best nation of the world
Direct our leaders path and give the humble spirit of followership to the masses
Father Lord, fill the bushel of resources on Nairaland to continue to be a source of inspiration to the world.
Grant peace unto the trouble hearted
Give hope to those in despair
and grace to the down-trodden

Thank you Lord, for in You and unto You I pray. Amen
Politics / Re: Fresh Gun Battle In Port Harcourt by richylaw(m): 1:56pm On Aug 17, 2007
Still finding it hard to believe it's eventually turned to this, come to think of it; the water lily does not dance to vague tunes, it surely has a drummer on the river bed. The military / government should strategise on how to pin down these guys's ammunitionists . A war without the arms is already an history before it starts at all.
PECULIAR NONSENSE!

1 Like

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:22pm On Aug 17, 2007
Nana rora jo ijo yen o.
Bolarge ma gbadun
Mishoo , fi awe yen sile, ikun n jogede ikun redi , ikun o mo wipe ohun ti o pa ohun lohun je. Ki Oluwa ma je ki a ba ojo olojo lo o.
Everyone in da house keep up the vibes, it FUUUURAIIIIDEEEEEY!
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 11:23am On Aug 17, 2007
A jiire o Mishoo, iwo na n ko se ara se girigir?. A de tun kuu ipari ose yi o.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:28pm On Aug 16, 2007
Egbe eye lo n to eye lehin.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:20pm On Aug 16, 2007
omoge jowo iwona ba Mishoo jo now, ara o sa gbodo sa fara! grin

Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:57pm On Aug 16, 2007
Mishoo, Omoge, Minute ati Bolarge mo ki yin kaabo si aagbon pataki yio. O se owo olosan ni agbegbe ti mo wa , sugbon mo mo wipe awon kan sese  n ji ni, bee si ni ojo n re bi ana lodo awon elomiran :Ise Olodumare awamaridi ni
Omo Oduduwa e gbonra jigi e je ka sise ori ran wa.

Bolarge:

@richylaw

Oluwa Ohh! shocked shocked shocked
Eeyan lo gbo ede abinibi to bayi. shocked shocked
Aaaah! richylaw mo juba o!
Abi ogbon kan wa te n tasi ni? grin

Oodua a tunbo maa gbe wa oh!
Ase!!
Ola Oluwa  ajenjetan.
Imo (wisdom) Oluwa  abu mu mo fa n'ikoko(water pot)
Laakaye Eledumare o ni won gbobgo wa o. Ko si ogbon kan ti o tun yato si wipe mo gbo (understand), mo ka (studied) ,mo gba (accepted and give regards), mo si mu ewa ede abinibi mi lo gege bii iwonba rebete ti Olorun yonda fun mi ninu ogbon.
Ore wa Bolarge, ko wa a ti pe ju , bi o ba wu o , o le da bi mi! o si tun le gbo ede yi ju emi na lo. Kiko ni mi mo

minute:

iyeen gangan ni mofe ko.

kini won pe yen? raara sisun ?
Eyi ti o ri ti mo ko yen  kii see Rara o, aroko oro iwuri lasanlasan ti ko ni amulumola ninu ni a lee kaa si. Jara mo ko ti pe ju, orun to wa loke yio sa aso gbe

Iya , iya mi,  mo n re ile oko
Loni , loni idi mi di idi ileke
Olomoge n lo di abileko
Oju mi yeso , o kuro ni t'omidan
huh huh huh
 cry cry cry

Eleyi ni a le pe ni Rara eyi ti a le lo lati fi sun ekun iyawo.
cheers all.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 10:11am On Aug 16, 2007
Minute

Inu mi dun gan ni si oro isiri  ti o tun  ju si ori afefe yi o. La i si ani ani mo ti ri mo daju wipe iwo kii se akata tabi ajereke rara. Sugbon dakun o ti o ba ri mi, o le ya o lenu wipe eni ti wa di mo ni mo ma je ati wipe kikunle yen,  awon agba ti o tun n be niwaju temi ni o wa fun o men I am still young shocked. Gegebi iwo ti se so , bi omode ba mo owo we yio ba awon agba jeun. Se o de tun ranti pe omode ojoun lo n di agba lola, eyin kan soso bayi ni si di akuko o. Minute 'omo agba' o ku akitiyan o. Pelupelu, emi ko ro wipe eko ede yoruba kan tun wa ti mo le ko e mo o,nitori o ti mo ede yi pe to. Awon 'ayaba-awon-iyo si oro' bii ewi ,oriki orile, ijala, rara, ege, iwi egungun ati bebelo nikan ni mo ro wipe o ku ti o ye ki o mo, ti o tun fi le lamilaaka ninu ede pipe. Ohun ti o si mu awon ewa ede yi yato si ra won ni ona ati ohun(voice) ti a fi n pe won jade ati paapaa julo awon jankowii asayan oro ti o n se esongbe fun okookan won. Nitorina , se kankan ki o si ta imo ede lokun , ki omo re to m bo lojo ola le roun sa aso le lori o. Oduduwa a gbe wa o. ASE.

Tafari ,olodo oba omo ateni gbore, o ku afiyesi, o si tun ku akiitiyan.
sebi bokun o ba gbe okiki re o ni tan!
b'osa o ba fa ariwo oruko re ko ni rinle
Gudugudu loba awon omele
wonsiwonsi loba awon sekere
Iyun loba ileke o ti da ju
Awoko loloba orin
Paapin bayi lolori awon fila
Tanganran si ni oga awon awo
Ori bayi la o ma je o , a o ni di iru lagbara Aseda aye, omimimile mi 'gi oko karakara, baba mi a dakeje fowo sa gbeji.
Awon oke ohun ni ko fe ja ka ri tihin o, sugbon ara le koko ni bi ota.
Mo ti pada de si ori igunwa bayi o.
Ka jo ma a 'rocky' loku.
Aye wa o ni polukurumusu o
A o ni jeegun kehin eran.
A o kere oko de ile o
ASE.

Gbogbo ara aba, lokunrin lobinrin, lomode ati lagba mo ki i yin ni tesoteso , mo ki yin ni tologuntologun.
Mishoo, Desorlah,Segoye,Nana,Ayanjide, Omoge, Aloib, Disguy, Debosky ati gbogbo oju titun;
Akotun la o ma ji siire o lagbara B'ami oke.
Agbe a ma gbere pade olokun o
Aluko a ma gbere pade olosa
Eyin lakeke foro si
Eyin ni kuluso n fi se fuja lawujo
Bo ti le je wipe iwaju bayi l'oka foro ti e si
Oro aye o ni ta wa o
ARAN (Velvet) LA O MA DA, A O NI D'ARAN (crime) o
IRE.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:15pm On Aug 14, 2007
omoge:

rombo rombo state ala kara gbe wa
rombo rombo state, rombo rombo state ala kara gbe wa oooo

wink
Se alakara de ti gbe de? Nitori mo ri wipe orin yen wo e lara gan ni o
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:06pm On Aug 14, 2007
E ku ikale o gbogbo eniyan, se mo ba gbogbo yin da.

minute :

richy and others, E ka re ooo

ti obirin (okurin) o ba she enu, alangba o le wo be lo


O dami loju wipe ohun ti o fe so ni yi, ' bi ogiri (monolithic wall) o ba la enu, alangba o le wobe.' Emi ko ri idi ti obinrin tabi okunrin yio se la enu fun alangba o grin. Minute ohun ti o ba je ki o mo ekuru pelu atadindin ati ila, ila elegusi , ikoko isaasun ati bebelo, o ti fihan gbangbangba wipe ile ti o mo iyi asa ounje ile youruba ni o ti wa, ogidi omo kaaro ojiire ni o. Koda bi o ti se n pe ede jade lenu lowolowo yii n je ki n se iye meji [[s]sup]e be like say u dey hide face before [/sup] [/s] Ju gbogbo re lo, e ku akitiyan

Dis guy mo n je o bi o se n ki mi o.
Mishoo, o ye ki o ti ri wipe ara Egun ni eni ti o n ba soro now, eyi ti o fi n ko ni yoruba , ko orin ilu won fun:
Eto jowe /x2
Ji le fonto
fe ne jato
Isokiriso
isokiriso
isokiri so so so grin
Desorlah aya Segoye eku itoju oko yin o, a n reti Oloye Segoye pada ninu ilu laipe
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:51pm On Aug 13, 2007
Mo ki gbogbo mutumuwa ti n be ni kale , wipe e ku ojo meta o. Se alaafia ni gbogbo ile wa o.
Mo se akiyesi wipe itu orisirisi ni awon ara ilu ti pa laarin bi ojo meji-meta ti mo lo irin ajo. Inu mi dun gan ni o. Aloib, Dblock, Disguy,Segoye, Tafari, Mishoo,Omoge, IyaAje ati Ayanjide, mo ki gbogbo yin o e ku owo iwaju o. Ola okankan wa o ni re ehin.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 6:27pm On Aug 09, 2007
egba re yen !
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:22pm On Aug 09, 2007
Alaafia fun o o Ayanjide
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 6:01am On Aug 09, 2007
Debosky: Fi Tafari sile o, emi na ti n wo be tele. A se padi ni ohun ati emi okunkun. Abajo ti o fi fe je oye ki o ba le wa da ilu ru. Agbedo ki a mari  shocked
Minute : Okan re bale o, se o ranti wipe mo ti so wipe emi ko ni tii igba kan bo ikan ninu! O didan ki a too ka to taa , a i jebe yio di eran idin.
Mishoo : Se oro ti wa ye o wayi, n je o ranti odu ti a ki fun Oba olufimo ninu Ayeyewontan?

Ayeyewontan iwa ibaje ni won n hu
A difa fun Olufimo Apopo ti o faya re moro
A pe 'je , ije o je o
A p'oro , Oro o mi titi o
E je a ye nu apeere oba wo.

Emi o ni se oro temi loro olufimo Apopo o.

Aloib: Pele omo Ibadan tooto, orin re yen de dun gan , o mu mi ranti iya mi Omoladun ( ki Olorun fi orun ke) . Awon ogidi omo Ibadan nu.
Iyalode Ika: Eyin na be ju wole, o da be. A bi emi Okunkun na ni o le yin pada ni. Tafari ti da nkan le o.
Tafari: Wahala wa o. eyi ti o tun so yi tun kamomo die o. O ti wa fihan wipe iwo ko ni fi okan awon omidan ati olomoge ilu yi bale pelu owo ati ogun re nu o. Ipade ilu ya, Baale stands up and leave for the palace meeting room
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:28pm On Aug 08, 2007
bo ya ki olorun fun rara re da o lohun.
A kii saju elee de p'eede
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 5:06pm On Aug 08, 2007
Arabinrin Nana , e ma wo le si ori okun yii o. Alaafia a ko bi?

Minute, ko si igba ti kukulaja ogun(war) de, ti iran(clan) eso Ikoyi o gbera nile , gbera e nija.
Ebe ba laa b'oke(mountain), kokoko laa ba ota (bullet), ninu oye ede ati ilera ti o peye ni mo wa.
O ti bere na niyen o. O le ko iwe ranse so wo si mi lori adiresi ori alantakun mi , iseabe@yahoo.com.
Ko si ewu legberun eko a fi aidun obe.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:28pm On Aug 08, 2007
Mishoo daadaa ni mo wa o. A dupe lowo Eledua wipe a si n fi olele je eko.

minute:

yeah that is  him.

what was your major in coll, yoruba language?
the way u type is what i'll call GBANKOGBI!

AND IM LOVIN IT!!
Minute I am an architect by profession and an animator/ modellist as specialization.
otooto laayo suku lara agbado
otooto la pa omo yo ninu awusa
otooto laayo igbin kuro ninu ikarahun
oto lede, oto lasa , oto si tun ni ki a le fi se gbajumo lawujo.
cheers.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:43pm On Aug 08, 2007
grin Yeah I know Kola Olootu the presenter.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:52pm On Aug 08, 2007
e ku ikale o gbogb ara ile :-p
Music/Radio / Re: Where Is Tosin Jegede (And Others)? by richylaw(m): 11:12am On Aug 07, 2007
Sophie, please I wouldn't mind having the onyeka's song as well . My email is: iseabe@yahoo.com
I will appreciate if someone could help me with 'o ti gbemi leke' by this same artiste.
cheers all
Politics / Re: Obasanjo Writes Semester Exam. Saying "I Am Not A Special Student" by richylaw(m): 9:54am On Aug 07, 2007
pisces20:

i wonder why he didn't take this decision before coming to contest for presidency in 1999 undecided

Then we may ask, how real or believable  was the Open University in 1999 ?
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:44pm On Aug 06, 2007
nana:

hm hm

beeni mo so!
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:30pm On Aug 06, 2007
Mishoo , se iwo o mo pe enikan ki gbe ina wo oju egun ni, enikan ki gbena woju ebora, a i je be ebora a bo laso. Iwo fi yen sile, je ki enikan wa danwo na. Onitohun o dan tan ni. he he he heh ehe he!
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 4:00pm On Aug 06, 2007
HELLO GAN NA NI . Desorlah , ka a si bi? o pe die ka to ri yin loni
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:15pm On Aug 06, 2007
mishoo:

Tafari, ko si ogba ti oro ki i si ni??
Se oo ti jawo loro oye yi na??
Amon a i san wo lo ile baale ooo.
Se o mo bee??


grin grin grin grin grin grin grin

Ile gbogbo ilu ni afin oba je, yara awon olori nikan l'enikan o gbodo be ju wo a fi baba funrare grin. N o mo reti awon alejo mi bo ba d'ojoro
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 3:00pm On Aug 06, 2007
Alagba Tafari , mo wa laafin ninu ola nla mi o. Koko la ra ota n le.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:58pm On Aug 06, 2007
Mo tun ki gbogbo wa ku ikale leekan si o. Mo ki awon eekan oro bi Alagba Tafari, Disguy, Mishoo ati Nana o. E ku ko le da.
Mishoo, inu mi dun wipe o tu ile kan Ilu Oyotunji o.  I got to know about  Oyotunji about four years ago. Mo si tun ti ni ohun kan tabi omiran se pelu awon abenugo ti n je ki eye ke bi eye ni Oyotunji. Boya ti awon omo yanmirin ode oni ba tun n ri eleyi won yio le pe aro ati odofin inu won wa ile , lati ri wipe ede ati asa ti o lami laaka julo lori ile agbaye (Yoruba!) ko paarun . Alagba Mishoo , e ku afiyesi . E si tun ku afokantan.
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:07pm On Aug 06, 2007
Nana , fi Mishoo sile o, o dabi eni wipe isu ewura n wu je ni grin
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 2:01pm On Aug 06, 2007
Nana ti n jeun soke re o. O dabi eni wipe o ma ni lati sanwo fun awon kan lori okun yi. Yoruba re ti n rin la i fe se ko wayi gebebi Mishoo ti so. This is interesting.more to come
Culture / Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:03pm On Aug 06, 2007
Mo ki onile ,
mo si tun ki alejo.
Mo ki majesin ,
mo si tun ki ara iwaju ti won f'ewu sori ti won si n fopa tile gbangbangban.
Mo ki gbogbo igbimo 'ko le da' mo si tun foye ati imo ki eni ti o ku die kaa to fun. Won ni ogbon lo so 'le aye ro, e so pele laa fi pa efon to ba ba le ni labe. Ojojumo bi mo ba ti ji awon oro ede kulubo kulubo a ma so kulu kulu kulu ni 'sale ikun mi. A ni se , mo ni won a ma ja mi je labe aso! Omo Yoruba atata, nibo le gbe gege ikowe yin si, nibo ni gbogbo 'alagbara karonwi ' lo? Ede yi o gbodo ku, ede yi o ni ku, ede yi kii ku. E ma tuyaya, ema tuyaya e je ka gbe ohun ti se tiwa laruge.
O wu mi ki n ma wi titi ale a fi le
o wu mi ki n ma to titi orun o fi wo
a lo n gbe mi lara ki n ma fo rere titi iyaleta.
A mo o aaye ni o po, asiko ni ko to , ki Oluwa ki o fun wa ni ibale ara.
Lasiko yi ki ilu wa ko maa gboro si o
Naijira o ni tuka
eye a ma ke bi eye
eku a ma dun bi eku
kaboyun le ko ma bi were
k'awon agan ki won ma towo ala bo osun, a ni se ki won ma rohun mu p'omo lara
eniti n sise o ni sise se
eni ti n wa , yio ba oloore pade o
Nairaland na o ni tu
awujo omo 'Kaaro ojire' na o ni daru
Mo ti ji loni o, mo ti ji sire
mo ti ji s'ola
Mo ti ji s'ayo
Mo ti ji si aiku ti se baale oro
Segoye se o jiire ?
Mishoo se o jiire ?
Tafari se o jiire ?
Nana se o jiire ?
Desorlar se o jiire ?
Debosky se o jiire ?
Haywhy se o jiire ?
WesleyanA se o jiire ?
Minute se o jiire ?
Omoge se o jiire ?
Omogenaija se o jiire ?
Ikamefa se o jiire ?
Dblock se o jiire ?
Aloib se o jiire ?
Israelite se o jiire ?
Champred se o jiire ?
Wunmi se o jiire ?
Kemoade se o jiire ?
Ayefele nko se o n be lalaafia ara?
Gbogbo eni ti n be nile ti n o ti ki, e dakun e mo fi se binu, gbogbo ara ni mo fi se e n le be n.
Mo ki gbogbo wa ni tesoteso , mo ki gbogbo wa ni tologun tologun
A o ni jabo o
A o ni ja fo o
Ka ma ba re pade o
Gbogbo wa a ti di awon agbagba owo ti won n rin ni owowo lo si ilu Owo lati lo ki Olowo to Owo, aye o ma fowo wa wo wa lo ni o. ASE O , ASE O, ASE NI T'OKE AGUNLA!
IRE
cry now the friday is gone and here stays a new week , but my hope is high , very high as it goes higher that another friday will come soon and many more will come smiley

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) (of 17 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 76
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.